1. Ní ọjọ́ kinni oṣù, ní ọdún kọkanla tí a dé ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀: ó ní,
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, nítorí pé àwọn ará ìlú Tire ń yọ̀ sí ìṣubú ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń sọ wí pé ìlẹ̀kùn ibodè àwọn eniyan yìí ti já, ibodè wọn sì ti ṣí sílẹ̀ fún wa, nisinsinyii tí ó di àlàpà, a óo ní àníkún.
3. “Nítorí náà, mo lòdì sí ọ, ìwọ Tire, n óo sì kó ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè wá gbógun tì ọ́, bíi ríru omi òkun.
4. Wọn óo wó odi Tire; wọn óo wó ilé-ìṣọ́ tí ó wà ninu rẹ̀ palẹ̀. N óo ha erùpẹ̀ inú rẹ̀ kúrò, n óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán.
5. Yóo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí láàrin òkun, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀; yóo sì di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
6. Ogun yóo kó àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”
7. OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun.