1. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo dájọ́, ṣé o óo dájọ́ ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí? Sọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀ fún un.
3. Sọ fún un pé èmi OLUWA Ọlọrun ní, ìwọ ìlú tí wọ́n ti ń paniyan ní ìpakúpa kí àkókò ìjìyà rẹ̀ lè tètè dé, ìlú tí ń fi oriṣa ba ara rẹ̀ jẹ́!