26. Ẹ ṣí fìlà, kí ẹ sì ṣí adé ọba kúrò lórí, gbogbo nǹkan kò ní wà bí wọ́n ṣe rí. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ gbé àwọn tí ipò wọn rẹlẹ̀ ga, kí ẹ sì rẹ àwọn tí ipò wọn wà lókè sílẹ̀.
27. Ìparun! Ìparun! N óo pa ìlú yìí run ni; ṣugbọn n kò ní tíì pa á run, títí ẹni tí ó ni í yóo fi dé, tí n óo sì fi lé e lọ́wọ́.
28. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí:‘A ti fa idà yọ, láti paniyan.A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná.
29. Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn.
30. “ ‘Dá idà náà pada sinu àkọ̀ rẹ̀. Ní ilẹ̀ rẹ ní ibi tí a ti dá ọ, ni n óo ti dá ọ lẹ́jọ́.
31. N óo bínú sí ọ lọpọlọpọ, ìrúnú mi yóo jó ọ bí iná, n óo fà ọ́ lé àwọn oníjàgídíjàgan lọ́wọ́, àwọn tí wọ́n mọ̀ bí wọ́n ṣe ń panirun.