7. Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
8. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti.
9. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀.
10. “Nítorí náà, mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wá sinu aṣálẹ̀.
11. Mo fún wọn ní òfin mi, mo sì fi ìlànà mi hàn wọ́n, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè.
12. Lẹ́yìn náà, mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi, kí ó máa jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi OLUWA yà wọ́n sí mímọ́.
13. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀.
14. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde.
15. Nítorí náà, mo búra fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n kò ní mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí pé n óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jù ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
16. Nítorí pé wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọn kò tẹ̀lé òfin mi, wọ́n sì ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, nítorí pé ọkàn wọn kò kúrò lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn.
17. “Sibẹsibẹ mo fojú àánú wò wọ́n, n kò pa wọ́n run sinu aṣálẹ̀.
18. Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀ pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn baba wọn rìn, kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé òfin wọn, tabi kí wọ́n bọ oriṣa wọn.
19. Mo ní èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. Ẹ máa rìn ní ọ̀nà mi, kí ẹ sì máa pa òfin mi mọ́.
20. Ẹ máa pa àwọn ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín.