9. Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.
10. Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbàtí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,nítorí ó rí omi lọpọlọpọ.
11. Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbárani a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀.