18. O mú aṣọ rẹ tí a ṣe ọnà sí lára, o dà á bò wọ́n. O gbé òróró ati turari mi kalẹ̀ níwájú wọn.
19. Bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ tí mo fún ọ. Mo fún ọ ní ìyẹ̀fun tí ó kúnná, ati òróró, ati oyin pé kí o máa jẹ, ṣugbọn o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
20. “O mú àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati àwọn ọmọ rẹ obinrin tí o bí fún mi, o fi wọ́n rú ẹbọ ohun jíjẹ fún àwọn oriṣa. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ni o pe ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè ẹ̀sìn rẹ,
21. tí o fi ọ̀bẹ dú àwọn ọmọ mi, o fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí àwọn oriṣa?
22. Nígbà tí ò ń ṣe àgbèrè ati gbogbo nǹkan ìríra rẹ, o kò ranti ìgbà èwe rẹ, nígbà tí o wà ní ìhòòhò goloto, tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀!”