Isikiẹli 12:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ẹni tí ó jẹ́ olórí láàrin wọn yóo gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́, yóo sì jáde kúrò nílùú. Yóo dá odi ìlú lu, yóo gba ibẹ̀ jáde. Yóo fi nǹkan bojú kí ó má ba à rí ilẹ̀.

13. N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí.

14. Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ.

15. “Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé.

16. N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

17. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

18. “Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ.

19. Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù.

20. Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

21. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

22. “Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’

23. Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ.

24. “Nítorí pé ìran irọ́ tabi àfọ̀ṣẹ ẹ̀tàn yóo dópin láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

25. Ṣugbọn èmi OLUWA yóo sọ ohun tí mo bá fẹ́ sọ, yóo sì ṣẹ. Kò ní falẹ̀ mọ́, ṣugbọn níṣojú ẹ̀yin ìdílé ọlọ̀tẹ̀, ni n óo sọ̀rọ̀, tí n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

26. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

Isikiẹli 12