7. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni yóo jogún nǹkan wọnyi. N óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ̀, òun náà yóo sì máa jẹ́ ọmọ mi.
8. Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.”
9. Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí ó mú àwo meje lọ́wọ́, tí ìparun ìkẹyìn meje wà ninu wọn, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní “Wá, n óo fi iyawo Ọ̀dọ́ Aguntan hàn ọ́.”
10. Ó bá gbé mi ninu ẹ̀mí lọ sí orí òkè ńlá kan tí ó ga, ó fi Jerusalẹmu ìlú mímọ́ náà hàn mí, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
11. Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara.
12. Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà.
13. Ìlẹ̀kùn mẹta wà ní ìhà ìlà oòrùn, mẹta wà ní ìhà àríwá, mẹta wà ni ìhà gúsù, mẹta wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.
14. Odi ìlú náà ní ìpìlẹ̀ mejila. Orúkọ mejila ti àwọn aposteli mejila ti Ọ̀dọ́ Aguntan wà lára wọn.
15. Ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá ìwọnlẹ̀ wúrà lọ́wọ́ láti fi wọn ìlú náà ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, ati odi rẹ̀.
16. Igun mẹrẹẹrin ìlú náà dọ́gba, bákan náà ni gígùn rẹ̀ ati ìbú rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọnlẹ̀ náà wọn ìlú náà. Bákan náà ni gígùn rẹ̀, ati ìbú rẹ̀, ati gíga rẹ̀. Ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹjọ (1500) ibùsọ̀.
17. Ó wá wọn odi rẹ̀, ó ga tó igba ẹsẹ̀ ó lé ogún (220) gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n eniyan tí angẹli náà ń lò.
18. Òkúta iyebíye ni wọ́n fi mọ odi náà. Wúrà ni gbogbo ìlú náà tí ó mọ́ gaara bíi dígí.