Ìṣe Àwọn Aposteli 4:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí Peteru ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Johanu wà lọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn alufaa ati olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn Sadusi bá dé.

2. Inú bí wọn nítorí wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan pé àwọn òkú yóo jí dìde. Wọ́n fi ajinde ti Jesu ṣe àpẹẹrẹ.

3. Wọ́n bá mú wọn, wọ́n tì wọ́n mọ́lé títí di ọjọ́ keji, nítorí ilẹ̀ ti ṣú.

4. Ṣugbọn ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́, iye wọn tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan.

Ìṣe Àwọn Aposteli 4