Ìṣe Àwọn Aposteli 3:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní agogo mẹta ọ̀sán, Peteru ati Johanu gòkè lọ sí Tẹmpili ní àkókò adura.

2. Ọkunrin kan wà tí wọn máa ń gbé wá sibẹ, tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá. Lojoojumọ, wọn á máa gbé e wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili tí à ń pè ní “Ẹnu Ọ̀nà Dáradára,” kí ó lè máa ṣagbe lọ́dọ̀ àwọn tí ń wọ inú Tẹmpili lọ.

3. Nígbà tí ó rí Peteru ati Johanu tí wọ́n fẹ́ wọ inú Tẹmpili, ó ní kí wọ́n ta òun lọ́rẹ.

4. Peteru ati Johanu tẹjú mọ́ ọn, Peteru ní, “Wò wá!”

5. Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan.

6. Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.”

Ìṣe Àwọn Aposteli 3