15. ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.”
16. Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù.
17. Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn.
18. Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.
19. Nígbà tí wọ́n dé Efesu, Paulu fi Pirisila ati Akuila sílẹ̀, ó lọ sinu ilé ìpàdé àwọn Juu, ó lọ bá àwọn Juu sọ̀rọ̀.