Hosia 5:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Wọn yóo mú mààlúù ati aguntan wá, láti fi wá ojurere OLUWA, ṣugbọn wọn kò ní rí i; nítorí pé, ó ti fi ara pamọ́ fún wọn.

7. Wọ́n ti hùwà aiṣootọ sí OLUWA; nítorí pé wọ́n ti bí ọmọ àjèjì. Oṣù tuntun ni yóo run àtàwọn, àtoko wọn.

8. Ẹ fọn fèrè ní Gibea, ẹ fọn fèrè ogun ní Rama, ẹ pariwo ogun ní Betafeni, ogun dé o, ẹ̀yin ará Bẹnjamini!

9. Efuraimu yóo di ahoro ní ọjọ́ ìjìyà; mo ti fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ dájúdájú hàn, láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli.

10. OLUWA wí pé: “Àwọn olórí ní Juda dàbí àwọn tí wọn ń yí ààlà ilẹ̀ pada, n óo da ibinu mi sórí wọn, bí ẹni da omi.

11. Ìyà ń jẹ Efuraimu, ìdájọ́ ìparun sì ti dé bá a, nítorí pé, ó ti pinnu láti máa tẹ̀lé ohun asán.

12. Nítorí náà, mo dàbí kòkòrò ajẹnirun sí Efuraimu, ati bí ìdíbàjẹ́ sí Juda.

13. “Nígbà tí Efuraimu rí àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ọgbẹ́ rẹ̀, Efuraimu sá tọ Asiria lọ, ó sì ranṣẹ sí ọba ńlá ibẹ̀. Ṣugbọn kò lè wo àìsàn Israẹli tabi kí ó wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn.

Hosia 5