10. Nípa ìfẹ́ Ọlọrun náà ni a fi yà wá sọ́tọ̀ nítorí ẹbọ tí Jesu fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
11. Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà.
12. Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.
13. Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀.
14. Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae.
15. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó kọ́kọ́ sọ báyìí pé,
16. “Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dánígbà tí ó bá yá, Èmi Oluwa ni mo sọ bẹ́ẹ̀,Èmi óo fi òfin mi sí ọkàn wọn,n óo kọ wọ́n sí àyà wọn.”
17. Ó tún ní, “N kò ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú wọn mọ́.”
18. Nígbà tí a bá ti dárí àwọn nǹkan wọnyi ji eniyan, kò tún sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.
19. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a ní ìgboyà láti wọ Ibi Mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ ìkélé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu,
20. nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀.
21. A tún ní alufaa àgbà tí ó wà lórí ìdílé Ọlọrun.
22. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa.
23. Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí.
24. Ẹ jẹ́ kí á máa rò nípa bí a óo ti ṣe fún ara wa ní ìwúrí láti ní ìfẹ́ ati láti ṣe iṣẹ́ rere.
25. Ẹ má jẹ́ kí á máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn mìíràn, ṣugbọn kí á máa gba ara wa níyànjú, pataki jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti rí i pé ọjọ́ ńlá ọ̀hún súnmọ́ tòsí.
26. Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.
27. Ohun tí ó kù ni pé kí á máa retí ìdájọ́ pẹlu ìpayà ati iná ńlá tí yóo pa àwọn ọ̀tá Ọlọrun.