Heberu 1:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ.

4. Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ.

5. Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,“Ìwọ ni ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ?”Tabi tí ó sọ fún pé,“Èmi yóo jẹ́ baba fún un,òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?”

6. Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé,“Kí gbogbo àwọn angẹliỌlọrun foríbalẹ̀ fún un.”

7. Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé,“Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù,tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”

8. Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé,“Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun,ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ.

Heberu 1