9. Ẹsita wú Hegai lórí, inú rẹ̀ dùn sí i pupọ. Ó fún un ní nǹkan ìpara ati oúnjẹ kíákíá. Ó tún fún un ní àwọn ọmọbinrin meje ninu àwọn iranṣẹbinrin tí wọ́n wà ní ààfin. Ó fún Ẹsita ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ní ibi tí ó dára jùlọ ní ibi tí àwọn ayaba ń gbé.
10. Ẹsita kò sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá, tabi ìdílé rẹ̀, fún ẹnikẹ́ni nítorí pé Modekai ti kìlọ̀ fún un pé kí ó má ṣe sọ nǹkankan nípa rẹ̀.
11. Lojoojumọ ni Modekai máa ń rìn sókè sódò níwájú àgbàlá ibi tí àwọn ayaba ń gbé, láti bèèrè alaafia Ẹsita, ati bí ó ti ń ṣe sí.
12. Kí wundia kankan tó lè lọ rí ọba, ó gbọdọ̀ kọ́ wà ninu ilé fún oṣù mejila, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn obinrin wọn. Oṣù mẹfa ni wọ́n fi ń kun òróró ati òjíá, wọn á sì fi oṣù mẹfa kun òróró olóòórùn dídùn ati ìpara àwọn obinrin.
13. Nígbà tí wundia kan bá ń lọ siwaju ọba, lẹ́yìn tí ó ba ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó yẹ, ó lè gba ohunkohun tí ó bá fẹ́ mú lọ láti ilé àwọn ayaba.