Ẹsira 6:10-13 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Kí wọ́n baà lè rú ẹbọ tí yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọrun ọ̀run, kí wọ́n sì lè máa gbadura ibukun fún èmi ati àwọn ọmọ mi.

11. Siwaju sí i, mo tún pàṣẹ pé, bí ẹnikẹ́ni bá rú òfin mi yìí, kí wọ́n yọ ọ̀kan ninu igi òrùlé rẹ̀; kí wọ́n gbẹ́ ẹ ṣóńṣó, kí wọ́n tì í bọ̀ ọ́ láti ìdí títí dé orí rẹ̀. Kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ààtàn.

12. Kí Ọlọrun, tí ó yan Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìn rẹ̀, pa ẹni náà run, kì báà ṣe ọba tabi orílẹ̀-èdè kan ni ó bá tàpá sí òfin yìí, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti wó ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu. Èmi Dariusi ọba ni mo pa àṣẹ yìí, ẹ sì gbọdọ̀ mú un ṣẹ fínnífínní.”

13. Tatenai, gomina, Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí Dariusi ọba pa fún wọn lẹ́sẹẹsẹ.

Ẹsira 6