Ẹkún Jeremaya 5:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa,Ṣe akiyesi ẹ̀sín wa.

2. Àwọn ilẹ̀ àjogúnbá ẹni ẹlẹ́ni,ilé wa sì ti di ti àwọn àjèjì.

3. A ti di aláìníbaba, ọmọ òrukànàwọn ìyá wa kò yàtọ̀ sí opó.

4. Owó ni a fi ń ra omi tí à ń mu,rírà ni a sì ń ra igi tí a fi ń dáná.

5. Àwọn tí wọn ń lépa wa ti bá wa,ó ti rẹ̀ wá, a kò sì ní ìsinmi.

6. A ti fa ara wa kalẹ̀ fún àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Asirianítorí oúnjẹ tí a óo jẹ.

7. Àwọn baba wa ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àwọn sì ti kú,ṣugbọn àwa ni à ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

8. Àwọn ẹrú ní ń jọba lé wa lórí,kò sì sí ẹni tí yóo gbà wá lọ́wọ́ wọn.

9. Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ,nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀.

Ẹkún Jeremaya 5