17. A wọ̀nà títí ojú wa di bàìbàì,asán ni ìrànlọ́wọ́ tí à ń retí jásí.A wọ̀nà títí fún ìrànlọ́wọ́lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò lè gbani là.
18. Àwọn eniyan ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wa,tóbẹ́ẹ̀ tí a kò lè rìn gaara ní ìgboro.Ìparun wa súnmọ́lé,ọjọ́ ayé wa ti níye,nítorí ìparun wa ti dé.
19. Àwọn tí wọn ń lépa wa yáraju idì tí ń fò lójú ọ̀run lọ.Wọ́n ń lé wa lórí òkè,wọ́n sì ba dè wá ninu aṣálẹ̀.
20. Ẹ̀mí àwa ẹni àmì òróró OLUWA bọ́ sinu kòtò wọn,OLUWA tí à ń sọ nípa rẹ̀ pé,lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni a óo máa gbé láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
21. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin ará Edomu,tí ń gbé ilẹ̀ Usi.Ṣugbọn ife náà yóo kọjá lọ́dọ̀ yín,ẹ óo mu ún ní àmuyó,ẹ óo sì tú ara yín síhòòhò.