Ẹkún Jeremaya 4:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. OLUWA bínú gidigidi,ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ jáde.OLUWA dá iná kan ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

12. Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aráyé kò gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀,pé ọ̀tá lè wọ ẹnubodè Jerusalẹmu.

13. Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wolii rẹ̀ ló fa èyí,ati àìdára àwọn alufaa rẹ̀,tí wọ́n pa olódodo láàrin ìlú.

14. Wọ́n ń káàkiri bí afọ́jú láàrin ìgboro,ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sọ wọ́n di aláìmọ́tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè fọwọ́ kan aṣọ wọn.

15. Àwọn eniyan ń kígbe lé wọn lórí pé;“Ẹ máa lọ! Ẹ̀yin aláìmọ́!Ẹ máa kóra yín lọ! Ẹ má fi ọwọ́ kan nǹkankan!”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe di ìsáǹsá ati alárìnkiri,nítorí àwọn eniyan ń wí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè pé,“Àwọn wọnyi kò gbọdọ̀ bá wa gbé pọ̀ mọ́.”

Ẹkún Jeremaya 4