Ẹkún Jeremaya 1:21-22 BIBELI MIMỌ (BM)

21. “Gbọ́ bí mo ti ń kérora,kò sí ẹnìkan tí yóo tù mí ninu.Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa ìyọnu mi;inú wọn sì dùn,pé ìwọ ni o kó ìyọnu bá mi.Jẹ́ kí ọjọ́ tí o dá tètè pé,kí àwọn náà lè dàbí mo ti dà.

22. “Ranti gbogbo ìwà ibi wọn,kí o sì jẹ wọ́n níyà;bí o ti jẹ mí níyà,nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

Ẹkún Jeremaya 1