Ẹkisodu 37:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ẹ̀ka mẹfa ni ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà; mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji.

19. Ó ṣe àwọn kinní kan bí òdòdó alimọndi mẹta mẹta sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà.

20. Ife mẹrin ni ó ṣe sórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí òdòdó alimọndi pẹlu ìrudi ati ìtànná rẹ̀.

21. Ìrudi kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó so mọ́ ara ọ̀pá fìtílà náà lọ́nà mẹtẹẹta.

22. Àṣepọ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà ati ẹ̀ka ara rẹ̀ ati ìrudi abẹ́ wọn; ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe wọ́n.

23. Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà.

24. Odidi talẹnti wúrà marundinlaadọrin ni ó lò lórí ọ̀pá fìtílà yìí ati àwọn ohun èlò tí wọ́n jẹ mọ́ ti ọ̀pá fìtílà.

25. Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ turari kan, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ rẹ̀ rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é pẹlu ìwo rẹ̀ mẹrẹẹrin.

26. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ati òkè ati ẹ̀gbẹ́ ati abẹ́ rẹ̀, ati ìwo rẹ̀ pẹlu, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀.

27. Ó da òrùka wúrà meji meji, ó jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí pẹpẹ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni-keji, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà.

28. Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá rẹ̀, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

29. Ó ṣe òróró ìyàsímímọ́ ati turari olóòórùn dídùn bí àwọn tí wọn ń ṣe turari ṣe máa ń ṣe é.

Ẹkisodu 37