Ẹkisodu 29:36-46 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Lojoojumọ ni kí o máa fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètùtù. O sì níláti máa rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún pẹpẹ náà nígbà tí o bá ń ṣe ètùtù fún un, ta òróró sí i láti yà á sí mímọ́.

37. Ọjọ́ meje ni o níláti fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ, kí o sì yà á sí mímọ́, nígbà náà ni pẹpẹ náà yóo di mímọ́, ohunkohun tí ó bá sì kan pẹpẹ náà yóo di mímọ́ pẹlu.

38. “Ohun tí o óo máa fi rú ẹbọ lórí pẹpẹ lojoojumọ ni: ọ̀dọ́ aguntan meji, tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan.

39. Fi ọ̀dọ́ aguntan kan rúbọ ní òwúrọ̀, sì fi ekeji rúbọ ní àṣáálẹ́.

40. Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀.

41. Àṣaálẹ́ ni kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ọtí waini fún ìtasílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti òwúrọ̀. Ẹbọ olóòórùn dídùn ni, àní ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.

42. Atọmọdọmọ yín yóo máa rúbọ sísun náà nígbà gbogbo lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ, níwájú OLUWA, níbi tí n óo ti máa bá yín pàdé, tí n óo sì ti máa bá yín sọ̀rọ̀.

43. Ibẹ̀ ni n óo ti máa bá àwọn eniyan Israẹli pàdé, ògo mi yóo sì máa ya ibẹ̀ sí mímọ́.

44. N óo ya àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà sí mímọ́, ati Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, kí wọ́n lè máa sìn mí gẹ́gẹ́ bí alufaa.

45. N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.

46. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

Ẹkisodu 29