Ẹkisodu 29:34-45 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Bí ẹran ìyàsímímọ́ ati burẹdi náà bá kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, fi iná sun ìyókù, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ nítorí pé mímọ́ ni.

35. “Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe sí Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni kí o fi yà wọ́n sí mímọ́.

36. Lojoojumọ ni kí o máa fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètùtù. O sì níláti máa rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún pẹpẹ náà nígbà tí o bá ń ṣe ètùtù fún un, ta òróró sí i láti yà á sí mímọ́.

37. Ọjọ́ meje ni o níláti fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ, kí o sì yà á sí mímọ́, nígbà náà ni pẹpẹ náà yóo di mímọ́, ohunkohun tí ó bá sì kan pẹpẹ náà yóo di mímọ́ pẹlu.

38. “Ohun tí o óo máa fi rú ẹbọ lórí pẹpẹ lojoojumọ ni: ọ̀dọ́ aguntan meji, tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan.

39. Fi ọ̀dọ́ aguntan kan rúbọ ní òwúrọ̀, sì fi ekeji rúbọ ní àṣáálẹ́.

40. Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀.

41. Àṣaálẹ́ ni kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ọtí waini fún ìtasílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti òwúrọ̀. Ẹbọ olóòórùn dídùn ni, àní ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.

42. Atọmọdọmọ yín yóo máa rúbọ sísun náà nígbà gbogbo lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ, níwájú OLUWA, níbi tí n óo ti máa bá yín pàdé, tí n óo sì ti máa bá yín sọ̀rọ̀.

43. Ibẹ̀ ni n óo ti máa bá àwọn eniyan Israẹli pàdé, ògo mi yóo sì máa ya ibẹ̀ sí mímọ́.

44. N óo ya àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà sí mímọ́, ati Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, kí wọ́n lè máa sìn mí gẹ́gẹ́ bí alufaa.

45. N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.

Ẹkisodu 29