Ẹkisodu 25:20-28 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Kí àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú, kí wọ́n kọjú sí ara wọn, kí àwọn mejeeji sì máa wo ìtẹ́ àánú náà.

21. Gbé ìtẹ́ àánú náà ka orí àpótí náà, kí o sì fi ẹ̀rí majẹmu tí n óo fún ọ sinu rẹ̀.

22. Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli.

23. “Fi igi akasia kan tabili kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji, kí ó fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀.

24. Yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì yọ́ ojúlówó wúrà sí gbogbo etí rẹ̀ yípo.

25. Lẹ́yìn náà, ṣe ìgbátí kan yíká etí tabili náà, kí ó fẹ̀ ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, kí o sì yọ́ wúrà bo ìgbátí náà yípo.

26. Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà mẹrin, kí o sì jó òrùka kọ̀ọ̀kan mọ́ ibi ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

27. Kí òrùka kọ̀ọ̀kan súnmọ́ ìgbátí tabili náà, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà.

28. Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà.

Ẹkisodu 25