Ẹkisodu 12:32-47 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Ẹ máa kó àwọn agbo mààlúù yín lọ, ati agbo aguntan yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ máa lọ; ṣugbọn ẹ súre fún èmi náà!”

33. Àwọn ará Ijipti bá ń kán àwọn eniyan náà lójú láti tètè máa lọ. Wọ́n ní bí wọn kò bá tètè lọ, gbogbo àwọn ni àwọn yóo di òkú.

34. Àwọn eniyan náà bá mú àkàrà tí wọ́n ti pò, ṣugbọn tí wọn kò tíì fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì fi aṣọ so ọpọ́n ìpòkàrà wọn, wọ́n gbé e kọ́ èjìká.

35. Àwọn eniyan náà ṣe bí Mose ti sọ fún wọn, olukuluku wọn ti tọ àwọn ará Ijipti lọ, wọ́n ti tọrọ ohun ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà ati aṣọ.

36. OLUWA sì jẹ́ kí wọ́n bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, gbogbo ohun tí wọ́n tọrọ pátá ni àwọn ará Ijipti fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe, tí wọ́n sì fi kó ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ará Ijipti lọ.

37. Àwọn eniyan Israẹli gbéra, wọ́n rìn láti Ramesesi lọ sí Sukotu. Iye àwọn eniyan náà tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkunrin, láìka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.

38. Ọpọlọpọ àwọn mìíràn ni wọ́n bá wọn lọ, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo aguntan ati agbo mààlúù.

39. Wọ́n mú ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n fi ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, nítorí pé lílé ni àwọn ará Ijipti lé wọn jáde, wọn kò sì lè dúró mú oúnjẹ mìíràn lọ́wọ́.

40. Àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ijipti jẹ́ irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430).

41. Ọjọ́ tí ó pé irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) gééré, tí wọ́n ti dé ilẹ̀ Ijipti; ni àwọn eniyan OLUWA jáde kúrò níbẹ̀.

42. Ṣíṣọ́ ni OLUWA ń ṣọ́ wọn ní gbogbo òru ọjọ́ náà títí ó fi kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn eniyan Israẹli ya alẹ́ ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, láti ìrandíran wọn. Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣọ́nà ní òru ní ìrántí òru àyájọ́ ọjọ́ náà.

43. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Òfin àjọ ìrékọjá nìwọ̀nyí: àlejò kankan kò gbọdọ̀ ba yín jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá.

44. Ṣugbọn àwọn ẹrú tí ẹ fi owó rà, tí ẹ sì kọ ní ilà abẹ́ lè bá yín jẹ ẹ́.

45. Àlejò kankan tabi alágbàṣe kò gbọdọ̀ ba yín jẹ ẹ́.

46. Ilé tí ẹ bá ti se oúnjẹ yìí ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ gbogbo rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ mú ninu ẹran rẹ̀ jáde, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ egungun rẹ̀.

47. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe ìrántí ọjọ́ yìí.

Ẹkisodu 12