Ẹkisodu 12:42 BIBELI MIMỌ (BM)

Ṣíṣọ́ ni OLUWA ń ṣọ́ wọn ní gbogbo òru ọjọ́ náà títí ó fi kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn eniyan Israẹli ya alẹ́ ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, láti ìrandíran wọn. Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣọ́nà ní òru ní ìrántí òru àyájọ́ ọjọ́ náà.

Ẹkisodu 12

Ẹkisodu 12:33-49