Nítorí tiyín gan-an ni OLUWA ṣe bínú sí mi, tí ó sì fi ibinu búra pé, n kò ní kọjá sí òdìkejì Jọdani, n kò sì ní dé ilẹ̀ dáradára náà, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.