Diutaronomi 29:19-29 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Kí irú ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu má baà dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pé ‘Kò séwu, bí mo bá fẹ́ mo lè ṣe orí kunkun kí n sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ ara mi.’ Èyí yóo kó ìparun bá gbogbo yín, ati àwọn tí wọn ń ṣe ibi ati àwọn tí wọn ń ṣe rere.

20. OLUWA kò ní dáríjì olúwarẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ibinu ńlá OLUWA ni yóo bá a. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sinu ìwé yìí yóo ṣẹ sí i lára, OLUWA yóo sì pa orúkọ olúwarẹ̀ rẹ́ kúrò láyé.

21. OLUWA yóo dojú kọ òun nìkan, láti ṣe é ní ibi láàrin gbogbo ẹ̀yà Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ègún tí ó wà ninu majẹmu, tí a kọ sinu ìwé òfin yìí.

22. “Nígbà tí àwọn arọmọdọmọ yín tí wọn kò tíì bí, ati àwọn àlejò tí wọ́n bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè bá rí ìpọ́njú, ati àrùn tí OLUWA yóo dà bo ilẹ̀ náà,

23. tí wọ́n bá rí i tí gbogbo ilẹ̀ náà ti di imí ọjọ́ ati iyọ̀, tí gbogbo rẹ di eérú, tí koríko kankan kò lè hù lórí rẹ̀, bíi ìlú Sodomu ati Gomora, Adima ati Seboimu, tí OLUWA fi ibinu ńlá parẹ́,

24. gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ ilẹ̀ yìí dà báyìí? Kí ló dé tí ibinu ńlá OLUWA fi dé sórí ilẹ̀ yìí?’

25. Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọn kò mú majẹmu OLUWA Ọlọrun ṣẹ, tí ó bá àwọn baba wọn dá nígbà tí ó kó wọn jáde ní ilẹ̀ Ijipti.

26. Wọ́n ń bọ àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí OLUWA kò sì fi lé wọn lọ́wọ́.

27. Ìdí nìyí tí inú fi bí OLUWA sí ilẹ̀ yìí, tí ó sì mú gbogbo ègún tí a kọ sinu ìwé yìí ṣẹ lé wọn lórí.

28. OLUWA sì fi ibinu ńlá ati ìrúnú lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn, ó sì fọ́n wọn dà sórí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.’

29. “Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí.

Diutaronomi 29