Diutaronomi 28:53-67 BIBELI MIMỌ (BM)

53. “Ojú yóo pọn yín tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá yin bá dó tì yín, tí yóo fi jẹ́ pé àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ni ẹ óo máa pa jẹ.

54. Ọkunrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn ọkunrin yín, yóo di ahun sí arakunrin rẹ̀, ati sí iyawo rẹ̀ tí ó fẹ́ràn jùlọ, ati sí ọmọ rẹ̀ tí ó kù ú kù,

55. tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní fún ẹnikẹ́ni jẹ ninu ẹran ara ọmọ rẹ̀ tí ó bá ń jẹ ẹ́; nítorí pé kò sí nǹkankan tí ó kù fún un mọ́, ninu ìnira tí àwọn ọ̀tá yín yóo kó yín sí nígbà tí wọ́n ba dó ti àwọn ìlú yín.

56. Obinrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn obinrin yín, tí kò jẹ́ fi ẹsẹ̀ lásán tẹ ilẹ̀ nítorí àwọ̀ rẹ̀ tí ó tutù ati ìwà afínjú rẹ̀, yóo di ahun sí ọkọ tí ó jẹ́ olùfẹ́ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin.

57. Yóo bímọ tán, yóo sì jẹ ibi ọmọ tí ó jáde lára rẹ̀ ní kọ̀rọ̀, yóo sì tún jẹ ọmọ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, nítorí pé kò sí ohun tí ó lè jẹ mọ́, nítorí àwọn ọ̀tá yín tí yóo dó ti àwọn ìlú yín.

58. “Bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò tẹ̀lé gbogbo òfin tí a kọ sinu ìwé yìí, pé kí ẹ máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó lẹ́rù, tí ó sì lógo,

59. OLUWA yóo mú ìpọ́njú ńlá bá ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, ìpọ́njú ńlá ati àìsàn burúkú, tí yóo wà lára yín fún ìgbà pípẹ́.

60. Gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n bà yín lẹ́rù, ni OLUWA yóo dà bò yín, tí yóo sì wà lára yín.

61. Àwọn àìsàn mìíràn ati ìpọ́njú tí wọn kò kọ sinu ìwé òfin yìí ni OLUWA yóo dà bò yín títí tí ẹ óo fi parun.

62. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹ kò ni kù ju díẹ̀ lọ mọ́, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín.

63. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ dídùn inú OLUWA láti ṣe yín ní rere ati láti sọ yín di pupọ, bákan náà ni yóo jẹ́ dídùn inú rẹ̀ láti ba yín kanlẹ̀ kí ó sì pa yín run. OLUWA yóo le yín kúrò lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.

64. OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí.

65. Ara kò ní rọ̀ yín rárá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí ìdí jókòó. OLUWA yóo mú jìnnìjìnnì ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ba yín, yóo sì mú kí ojú yín di bàìbàì.

66. Ninu hílàhílo ni ẹ óo máa wà nígbà gbogbo, ninu ẹ̀rù ati ìpayà ni ẹ óo máa wà tọ̀sán-tòru.

67. Àwọn ohun tí ojú yín yóo máa rí yóo kó ìpayà ati ẹ̀rù ba yín, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ilẹ̀ bá ti ṣú, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti mọ́; bí ilẹ̀ bá sì ti tún mọ́, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti ṣú.

Diutaronomi 28