Diutaronomi 28:45-50 BIBELI MIMỌ (BM)

45. “Gbogbo ègún wọnyi ni yóo ṣẹ si yín lára, tí yóo sì lẹ̀ mọ́ yín pẹ́kípẹ́kí títí tí ẹ óo fi parun, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò pa òfin rẹ̀ mọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé àwọn ìlànà tí ó pa láṣẹ fun yín.

46. Àwọn ègún náà yóo wà lórí yín gẹ́gẹ́ bí àmì ati ohun ìyanu, ati lórí àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

47. Nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun bukun yín, ẹ kọ̀, ẹ kò sìn ín pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn.

48. Nítorí náà, ní ìhòòhò, pẹlu ebi ati òùngbẹ, ati àìní ni ẹ óo fi máa sin àwọn ọ̀tá tí OLUWA yóo rán si yín, yóo sì la àjàgà irin bọ̀ yín lọ́rùn títí tí yóo fi pa yín run.

49. OLUWA yóo gbé orílẹ̀-èdè kan, tí ẹ kò gbọ́ èdè wọn, dìde si yín láti òpin ayé; wọn óo yára bí àṣá.

50. Ojú gbogbo wọn óo pọ́n kankan, wọn kò ní ṣàánú ọmọde, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní bọ̀wọ̀ fún àgbà.

Diutaronomi 28