8. “Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú.
9. “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sáàrin àwọn àjàrà tí ẹ bá gbìn sinu ọgbà àjàrà yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àjàrà náà, ati ohun tí ẹ gbìn sáàrin rẹ̀ yóo di ti ibi mímọ́.
10. “Ẹ kò gbọdọ̀ so àjàgà kan náà mọ́ akọ mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́rùn, láti fi wọ́n ṣiṣẹ́ ninu oko.
11. “Ẹ kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí wọ́n bá pa irun pọ̀ mọ́ òwú hun.
12. “Ẹ gbọdọ̀ fi oko wọnjanwọnjan sí igun mẹrẹẹrin aṣọ ìbora yín.
13. “Bí ẹnìkan bá gbé ọmọge níyàwó, ṣugbọn tí ó kórìíra rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀,
14. tí ó wá sọ pé ó ti ṣe ìṣekúṣe, tí ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ burúkú, tí ó bá wí pé, ‘Mo gbé obinrin yìí níyàwó ṣugbọn nígbà tí mo súnmọ́ ọn, n kò bá a nílé.’
15. “Kí baba ati ìyá ọmọbinrin yìí mú aṣọ ìbálé rẹ̀ jáde, kí wọ́n sì mú un tọ àwọn àgbààgbà ìlú náà lọ ní ẹnubodè.
16. Kí baba ọmọ náà wí fún wọn pé, ‘Mo fi ọmọbinrin mi yìí fún ọkunrin yìí ní aya, lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀ tán,
17. ó fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ìṣekúṣe. Ó ní, “N kò bá ọmọ rẹ nílé.” ’ Kí baba ọmọbinrin tẹ́ aṣọ ìbálé rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn àgbààgbà, kí ó sì wí pé, ‘Èyí ni ẹ̀rí pé ó bá ọmọ mi nílé.’
18. Àwọn àgbààgbà ìlú náà yóo mú ọkunrin yìí, wọn yóo nà án dáradára.