1. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo mààlúù tabi aguntan arakunrin yín, kí ó máa ṣìnà lọ, kí ẹ sì mójú kúrò, ẹ níláti fà á tọ olówó rẹ̀ lọ.
2. Bí ibi tí olówó ẹran ọ̀sìn yìí ń gbé bá jìnnà jù, tabi tí ẹ kò bá mọ ẹni náà, ẹ níláti fa ẹran ọ̀sìn náà wálé, kí ó sì wà lọ́dọ̀ yín títí tí olówó rẹ̀ yóo fi máa wá a kiri. Nígbà tí ó bá ń wá a, ẹ níláti dá a pada fún un.
3. Bákan náà ni ẹ níláti ṣe, tí ó bá jẹ́ pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni ó sọnù, tabi aṣọ rẹ̀, tabi ohunkohun tí ó bá jẹ́ ti arakunrin yín, tí ó bá sọnù tí ẹ sì rí i. Ẹ kò gbọdọ̀ mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i.
4. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù arakunrin yín, tí ó wó lulẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, kí ẹ sì mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i. Ẹ níláti ràn án lọ́wọ́ láti gbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù rẹ̀ dìde.
5. “Obinrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti ọkunrin, bẹ́ẹ̀ sì ni ọkunrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti obinrin nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìríra ni ó jẹ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín.
6. “Bí ẹ bá rí ìtẹ́ ẹyẹ lórí igi tabi ní ilẹ̀, tí ẹyin tabi ọmọ bá wà ninu rẹ̀, tí ìyá ẹyẹ yìí bá ràdọ̀ bò wọ́n, tabi tí ó bá sàba lé ẹyin rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ ẹyẹ náà pẹlu ìyá wọn.
7. Ẹ níláti fi ìyá wọn sílẹ̀ kí ó máa lọ ṣugbọn ẹ lè kó àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ láyé.