9. OLUWA sọ fún mi pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ da àwọn ará Moabu láàmú, tabi kí ẹ gbógun tì wọ́n; nítorí pé n kò fun yín ní ilẹ̀ wọn, nítorí pé mo ti fi ilẹ̀ Ari fún àwọn ọmọ Lọti gẹ́gẹ́ bí ohun ìní wọn.’ ”
10. (Ìran àwọn òmìrán kan tí à ń pè ní Emimu ní ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Wọ́n pọ̀, wọ́n sì lágbára. Wọ́n ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki.
11. Wọn a máa pè wọ́n ní Refaimu gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Anakimu, ṣugbọn àwọn ará Moabu ń pè wọ́n ní Emimu.
12. Àwọn ará Hori ni wọ́n ń gbé òkè Seiri tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn ọmọ Esau ti gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti pa wọ́n run. Wọ́n bá tẹ̀dó sórí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hori gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli náà ti tẹ̀dó sórí ilẹ̀ tí wọ́n gbà, tí OLUWA fún wọn.)
13. “Ẹ dìde nisinsinyii kí ẹ sì kọjá sí òdìkejì odò Seredi. A sì ṣí lọ sí òdìkejì odò Seredi.