7. ó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ níwájú OLUWA.
8. Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà.
9. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń hù.
10. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, kì báà ṣe ọmọ rẹ̀ obinrin tabi ọkunrin. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ máa wo iṣẹ́ kiri tabi kí ó di aláfọ̀ṣẹ tabi oṣó;
11. tabi kí ó máa sa òògùn sí ẹlòmíràn, tabi kí ó máa bá àwọn àǹjọ̀nú sọ̀rọ̀, tabi kí ó di abókùúsọ̀rọ̀.
12. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi di ohun ìríra níwájú OLUWA, ati pé nítorí ohun ìríra wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín ṣe ń lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fun yín.