20. Ẹ̀tọ́ nìkan ṣoṣo ni kí ẹ máa ṣe, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ sì lè jogún ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.
21. “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin igikígi bí igi oriṣa Aṣera sí ẹ̀bá pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, nígbà tí ẹ bá ń kọ́ ọ.
22. Ẹ kò sì gbọdọ̀ ri òpó mọ́lẹ̀ kí ẹ máa bọ ọ́, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín kórìíra wọn.