1. “Ní ọdún keje-keje ni kí ẹ máa ṣe ìdásílẹ̀.
2. Bí ẹ óo ṣe máa ṣe ìdásílẹ̀ náà nìyí: ẹnikẹ́ni tí aládùúgbò rẹ̀, tíí ṣe arakunrin rẹ̀, bá jẹ ní gbèsè kò ní gba ohun tí aládùúgbò rẹ̀ jẹ ẹ́ mọ́, nítorí pé, a ti kéde ìdásílẹ̀ tíí ṣe ti OLUWA.
3. Bí ó bá jẹ́ pé àlejò ni ó jẹ ẹni náà ní gbèsè, olúwarẹ̀ lè gbà á, ṣugbọn ohunkohun tí ó bá jẹ́ tiyín, tí ó wà lọ́wọ́ arakunrin yín, ẹ kò gbọdọ̀ gbà á pada.
4. “Ṣugbọn kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo jẹ́ talaka, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín, ní ilẹ̀ tí ó fun yín láti gbà,
5. bí ẹ bá sá ti gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì farabalẹ̀, ti ẹ tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí.
6. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Ẹ óo máa yá àwọn orílẹ̀-èdè ni nǹkan, ṣugbọn ẹ kò ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. Ẹ óo máa jọba lórí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ṣugbọn wọn kò ní jọba lórí yín.
7. “Bí ẹnìkan ninu yín, tí ó jẹ́ arakunrin yín, bá jẹ́ talaka, tí ó sì wà ninu ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ dijú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ háwọ́ sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka yìí.