6. ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli.
7. Ẹ ti fi ojú rí gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA ṣe.
8. “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà.
9. Kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fún wọn ati àwọn arọmọdọmọ wọn. Ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó sì ní ẹ̀tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin.
10. Nítorí pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà yìí, kò rí bí ilẹ̀ Ijipti níbi tí ẹ ti jáde wá; níbi tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn yín tán, ẹ óo ṣe wahala láti bu omi rin ín, bí ìgbà tí à ń bu omi sí ọgbà ẹ̀fọ́.