17. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun àwọn ọlọ́run, ati OLUWA àwọn olúwa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù ni Ọlọrun yín, kì í ṣe ojuṣaaju, kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
18. A máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn aláìníbaba ati àwọn opó. Ó fẹ́ràn àwọn àlejò, a sì máa fún wọn ní oúnjẹ ati aṣọ.
19. Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn àwọn àlejò; nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Ijipti rí.
20. Ẹ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín; ẹ sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.