Daniẹli 7:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán,mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́.Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀,aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú.Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun,ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná,kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná.

10. Iná ń ṣàn jáde bí odò níwájú rẹ̀.Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn tí ń ṣe iranṣẹ fún un,ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni àwọn tí wọ́n dúró níwájú rẹ̀.Ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀, a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀.

11. “Mo wò yíká nítorí ọ̀rọ̀ ńláńlá tí ìwo kékeré yìí ń fi ẹnu sọ, mo sì rí i tí wọ́n pa ẹranko náà, tí wọ́n sì jó òkú rẹ̀ níná.

12. Ní ti àwọn ẹranko tí ó kù, a gba àṣẹ wọn, ṣugbọn a dá wọn sí fún àkókò kan, àní fún ìgbà díẹ̀.

13. “Ninu ìran, lóru, mo rí ẹnìkan tí ó rí bí Ọmọ Eniyan ninu awọsanma, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Ẹni Ayérayé náà, ó sì fi ara rẹ̀ hàn níwájú rẹ̀.

14. A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun.

15. “Ìran tí mo rí yìí bà mí lẹ́rù pupọ, ọkàn mi sì dààmú.

16. Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní,

17. ‘Àwọn ọba ńlá mẹrin tí yóo jẹ láyé ni àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin tí o rí.

18. Ṣugbọn àwọn eniyan mímọ́ Ẹni Gíga Jùlọ yóo gba ìjọba ayé, ìjọba náà yóo jẹ́ tiwọn títí lae, àní títí ayé àìlópin.’

Daniẹli 7