4. Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.”
5. Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.
6. Ṣugbọn bí ẹ bá rọ́ àlá náà, tí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹ óo gba ẹ̀bùn, ìdálọ́lá ati ẹ̀yẹ ńlá, nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
7. Wọ́n dá ọba lóhùn lẹẹkeji pé, “Kí kabiyesi rọ́ àlá rẹ̀ fún wa, a óo sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
8. Ọba dá wọn lóhùn pé, “Mo mọ̀ dájú pé ẹ kàn fẹ́ máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò ni, nítorí ẹ ti mọ̀ pé bí mo ti wí ni n óo ṣe.
9. Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
10. Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí.
11. Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”
12. Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run.
13. Àṣẹ jáde lọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n; wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n.
14. Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, tí ọba pàṣẹ fún pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni; ó fi ọgbọ́n ati ìrẹ̀lẹ̀ bá a sọ̀rọ̀,
15. ó ní, “Kí ló dé tí àṣẹ ọba fi le tó báyìí?” Arioku bá sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí fún un.
16. Lẹsẹkẹsẹ, Daniẹli lọ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba pé kí ó dá àkókò fún òun, kí òun lè wá rọ́ àlá náà fún ọba, kí òun sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.