10. Lẹ́yìn ogún ọdún tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀,
11. tí Hiramu, ọba Tire sì ti fún un ní ìwọ̀n igi kedari, igi sipirẹsi ati wúrà tí ó fẹ́, fún iṣẹ́ náà, Solomoni fún Hiramu ní ogún ìlú ní agbègbè Galili.
12. Ṣugbọn nígbà tí Hiramu ọba wá láti Tire tí ó rí àwọn ìlú tí Solomoni fún un, wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn rárá.
13. Ó bi Solomoni pé, “Arakunrin mi, irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí?” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ilẹ̀ náà ní Kabulu títí di òní olónìí.
14. Ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni Hiramu ti fi ranṣẹ sí Solomoni ọba.