Àwọn Ọba Kinni 8:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń gbé Àpótí Ẹ̀rí náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ẹni tí ó bá dúró ninu Ibi-Mímọ́ fi lè rí orí wọn níwájú Ibi-Mímọ́ ti inú. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí wọn láti ìta. Àwọn ọ̀pá náà wà níbẹ̀ títí di òní yìí.

9. Kò sí ohunkohun ninu Àpótí Ẹ̀rí náà, àfi tabili òkúta meji tí Mose kó sinu rẹ̀ ní òkè Sinai, níbi tí OLUWA ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu, nígbà tí wọn ń ti Ijipti bọ̀.

10. Bí àwọn alufaa ti jáde láti inú Ibi-Mímọ́ náà, ìkùukùu kún inú rẹ̀,

11. tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò lè dúró láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, nítorí ògo OLUWA kún inú ilé OLUWA.

12. Solomoni bá gbadura, ó ní, “OLUWA, ìwọ ni o fi oòrùn sí ojú ọ̀run,ṣugbọn sibẹsibẹ o yàn láti gbé inú ìkùukùuati òkùnkùn biribiri.

13. Nisinsinyii mo ti kọ́ ilé kan tí ó lọ́lá fún ọ,níbi tí o óo máa gbé títí lae.”

14. Solomoni ọba yipada, ó kọjú sí àwọn eniyan níbi tí wọ́n dúró sí, ó sì súre fún wọn.

15. Ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ìlérí tí ó ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ, tí ó ní,

Àwọn Ọba Kinni 8