1. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà Israẹli: àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ati gbogbo àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan, ó pè wọ́n jọ sí Jerusalẹmu láti gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu ilé OLÚWA.
2. Gbogbo wọ́n bá péjọ siwaju rẹ̀ ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù Etanimu, tíí ṣe oṣù keje ọdún.
3. Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn àgbààgbà ti péjọ, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí náà.
4. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa gbé Àpótí OLUWA wá, ati Àgọ́ OLUWA, ati àwọn ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu rẹ̀.
5. Solomoni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli péjọ níwájú Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, wọ́n sì fi ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù tí ẹnikẹ́ni kò lè kà rúbọ.
6. Lẹ́yìn náà, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu ibi mímọ́ ti inú, ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kerubu.