Àwọn Ọba Kinni 15:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Gbogbo àwọn ohun èlò pẹlu wúrà ati fadaka tí baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati àwọn tí òun pàápàá yà sọ́tọ̀, ni ó dá pada sinu ilé OLUWA.

16. Nígbà gbogbo ni Asa ọba Juda, ati Baaṣa, ọba Israẹli ń gbógun ti ara wọn, ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà lórí oyè.

17. Baaṣa gbógun ti ilẹ̀ Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi yí Rama po, kí ẹnikẹ́ni má baà rí ààyè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, tabi kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

Àwọn Ọba Kinni 15