Àwọn Ọba Kinni 10:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Solomoni ọba fi igi alimugi náà ṣe òpó ilé OLUWA ati ti ààfin rẹ̀. Ó tún lò ninu wọn, ó fi ṣe ohun èlò orin tí wọ́n ń pè ní hapu ati gòjé fún àwọn akọrin rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò rí irú igi alimugi bẹ́ẹ̀ mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí di òní olónìí.

13. Gbogbo ohun tí ọbabinrin Ṣeba fẹ́, tí ó tọrọ lọ́wọ́ Solomoni pátá ni Solomoni fún un, láìka ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n ti kọ́ fi ṣe é lálejò. Ọbabinrin náà pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá pada sí ilẹ̀ wọn.

14. Ọtalelẹgbẹta ó lé mẹfa (666) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni ó ń wọlé fún Solomoni ọba lọdọọdun,

15. láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ń san fún un, èyí tí ń wá láti ibi òwò rẹ̀, ati èyí tí àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina ilẹ̀ Israẹli ń san.

16. Solomoni ṣe igba (200) apata wúrà ńláńlá, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli.

17. Ó sì tún ṣe ọọdunrun (300) apata wúrà kéékèèké, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n mina mẹta mẹta. Solomoni ọba kó gbogbo apata wọnyi sinu Ilé Igbó Lẹbanoni.

Àwọn Ọba Kinni 10