Àwọn Ọba Kinni 1:6-8 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Adonija yìí ni wọ́n bí tẹ̀lé Absalomu, ó jẹ́ arẹwà ọkunrin; baba rẹ̀ kò sì fi ìgbà kan dojú kọ ọ́ kí ó bá a wí nítorí ohunkohun rí.

7. Adonija lọ jíròrò pẹlu Joabu, ọmọ Seruaya, ati Abiatari alufaa, àwọn mejeeji tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

8. Ṣugbọn Sadoku alufaa, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, ati Natani wolii, ati Ṣimei, Rei, ati àwọn akọni Dafidi kò faramọ́ ohun tí Adonija ṣe, wọn kò sì sí lẹ́yìn rẹ̀.

Àwọn Ọba Kinni 1