27. Ǹjẹ́ kabiyesi ha lè lọ́wọ́ sí irú nǹkan báyìí; kí ó má tilẹ̀ sọ ẹni tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀?”
28. Dafidi ọba bá ní kí wọ́n pe Batiṣeba pada wọlé. Ó bá pada wá siwaju ọba.
29. Ọba bá búra fún un pé, “Mo ṣe ìlérí fún ọ ní orúkọ OLUWA Alààyè, tí ó gbà mí ninu gbogbo ìyọnu mi,
30. pé lónìí ni n óo mú ìbúra tí mo búra fún ọ ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣẹ, pé, Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn mi.”
31. Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Kabiyesi, oluwa mi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn.”
32. Ọba bá ranṣẹ pe Sadoku, alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, gbogbo wọ́n sì pésẹ̀ sọ́dọ̀ ọba.