Àwọn Ọba Keji 9:28-30 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi.

29. Ahasaya jọba ní ilẹ̀ Juda ní ọdún kọkanla tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli.

30. Nígbà tí Jehu dé Jesireeli, Jesebẹli gbọ́; ó lé tìróò, ó di irun rẹ̀, ó sì ń yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé ní òkè.

Àwọn Ọba Keji 9