26. Gbogbo nǹkan yòókù tí Pekahaya ṣe, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
27. Ní ọdún kejilelaadọta tí Asaraya jọba ní Juda, ni Peka, ọmọ Remalaya, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ogún ọdún.
28. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.
29. Ní àkókò tí Peka jọba Israẹli ni Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gba ìlú Ijoni, Abeli Beti Maaka, Janoa, Kedeṣi, Hasori, ati ilẹ̀ Gileadi, Galili ati gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rú lọ sí Asiria.
30. Ní ogún ọdún tí Jotamu, ọmọ Usaya jọba Juda, ni Hoṣea, ọmọ Ela, dìtẹ̀ mọ́ Peka ọba, ó pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀.
31. Gbogbo nǹkan yòókù tí Peka ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
32. Ní ọdún keji tí Peka ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Jotamu, ọmọ Usaya, jọba ní Juda.
33. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọ Sadoku.
34. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀ sí ọ̀nà Usaya, baba rẹ̀.
35. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run, àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. Òun ni ó kọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìhà àríwá ilé OLUWA.