19. Pulu, tí à ń pè ní Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli; kí ó baà lè ran Menahemu lọ́wọ́ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, Menahemu fún un ní ẹgbẹrun (1,000) talẹnti owó fadaka.
20. Ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ Israẹli ni ọba ti gba owó náà, ó pàṣẹ pé kí olukuluku dá aadọta ṣekeli owó fadaka. Ọba Asiria bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.
21. Gbogbo nǹkan yòókù tí Menahemu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
22. Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀, Pekahaya, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
23. Nígbà tí ó di aadọta ọdún tí Asaraya jọba ní Juda, ni Pekahaya, ọmọ Menahemu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji.